9 Ẹ kọ wọ́n sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín, ati sí ara ẹnu ọ̀nà ìta ilé yín.
10 “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mu yín wọ ilẹ̀ tí ó búra fún Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba yín, pé òun yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí wọ́n dára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ tẹ̀ wọ́n dó,
11 ati àwọn ilé tí ó kún fún àwọn nǹkan dáradára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ kó wọn sibẹ, ati kànga omi, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbẹ́ ẹ, ati àwọn ọgbà àjàrà ati igi olifi tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbìn ín. Nígbà tí ẹ bá jẹ, tí ẹ yó tán,
12 ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà gbàgbé OLUWA tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti jẹ́ ẹrú.
13 Ẹ gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa sìn ín. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra.
14 Ẹ kò gbọdọ̀ bọ èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín ń bọ,
15 nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọrun tíí máa ń jowú ni; kí inú má baà bí OLUWA Ọlọrun yín sí yín, kí ó sì pa yín run kúrò lórí ilẹ̀ ayé.