30 ọmọọ́lé, ọ̀ni, aláǹgbá, agílíńtí ati alágẹmọ.
31 Wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
32 Ohunkohun tí òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, ìbáà jẹ́ ohun èlò igi, tabi aṣọ tabi awọ, tabi àpò, irú ohun èlò yòówù tí ó lè jẹ́, ó níláti di fífọ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn náà, yóo di mímọ́.
33 Bí èyíkéyìí ninu wọn bá jábọ́ sórí ohun èlò amọ̀, gbogbo ohun tí ó bá wà ninu ohun èlò amọ̀ náà di aláìmọ́, fífọ́ ni kí o fọ́ ohun èlò náà.
34 Ohunkohun tí ó bá jẹ́ jíjẹ tí ó bá wà ninu ìkòkò amọ̀ yìí, tabi tí omi inú rẹ̀ bá ta sí lára, di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá jẹ́ mímu, tí ó wà ninu rẹ̀ náà di aláìmọ́.
35 Ohunkohun tí apákan ninu òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, kì báà jẹ́ ààrò tabi àdògán, o gbọdọ̀ fọ́ ọ túútúú; wọ́n jẹ́ aláìmọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ jẹ́ aláìmọ́ fun yín.
36 Tí ó bá jẹ́ odò, tabi kànga tí ó ní omi ni, wọn kì í ṣe aláìmọ́, ṣugbọn gbogbo nǹkan yòókù tí ó fara kan òkú wọn di aláìmọ́.