38 Ṣugbọn bí eniyan bá da omi lé èso náà lórí, tí apákan ninu òkú wọn sì já lé èso náà, ó di aláìmọ́ fun yín.
39 “Bí ọ̀kankan ninu àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
40 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ òkú ẹran náà níláti fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá ru òkú ẹran náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.
41 “Ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìríra, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ́.
42 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá ń fi àyà wọ́, tabi ohunkohun tí ó bá ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn tabi ohunkohun tí ó ní ọpọlọpọ ẹsẹ̀, tabi ohunkohun tí ó ń fà lórí ilẹ̀, nítorí ohun ìríra ni wọ́n.
43 Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di ìríra; ẹ kò gbọdọ̀ kó ẹ̀gbin bá ara yín, kí ẹ má baà di aláìmọ́.
44 Nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí mímọ́ ni èmi Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di aláìmọ́.