50 Kí alufaa yẹ àrùn náà wò, kí ó sì ti aṣọ tí àrùn náà ràn mọ́ mọ́lé fún ọjọ́ meje.
51 Kí ó yẹ àrùn ara aṣọ náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ti tàn káàkiri lára aṣọ tabi awọ náà, ohun yòówù tí wọ́n lè máa fi aṣọ náà ṣe, irú ẹ̀tẹ̀ tí ó máa ń ràn káàkiri ni; kò mọ́.
52 Kí alufaa jó aṣọ náà, ibi yòówù tí àrùn náà lè wà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohunkohun tí wọ́n fi awọ ṣe; nítorí pé irú àrùn tí ó máa ń ràn káàkiri ara ni; jíjó ni kí wọ́n jó o níná.
53 “Bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà kò bá ràn káàkiri lára aṣọ náà tabi ohun èlò awọ náà,
54 alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohun èlò tí àrùn wà lára rẹ̀ yìí, yóo sì tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i.
55 Alufaa yóo tún yẹ ohun èlò tí àrùn náà ràn mọ́ wò lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọ̀ ọ́. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn yìí ràn mọ́ kò bá mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tàn káàkiri sí i; sibẹ kò mọ́; jíjó ni ó níláti jó o níná, kì báà jẹ́ iwájú, tabi ẹ̀yìn aṣọ tabi awọ náà ni àrùn ràn mọ́.
56 Ṣugbọn nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí ó sì rí i pé àrùn náà ti wòdú lẹ́yìn tí a fọ aṣọ náà, kí ó gé ọ̀gangan ibẹ̀ kúrò lára ẹ̀wù, tabi aṣọ, tabi awọ náà.