25 Yóo pa àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, yóo sì mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.
26 Alufaa yóo bu díẹ̀ ninu òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀,
27 yóo ti ìka bọ inú òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì yìí, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ níwájú OLUWA nígbà meje.
28 Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu òróró tí ó wà ni ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn.
29 Alufaa yóo mú òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ yóo sì fi ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́, láti fi ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.
30 Yóo fi èyí tí apá rẹ̀ bá ká rúbọ: yálà àdàbà tabi ẹyẹlé;
31 ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.