31 ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.
32 Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, ṣugbọn tí apá rẹ̀ kò ká àwọn ohun ìrúbọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀.”
33 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,
34 “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí n óo fun yín, tí yóo jẹ́ ohun ìní yín, bí mo bá fi àrùn ẹ̀tẹ̀ sí ilé kan ninu ilẹ̀ yín.
35 Ẹni tí ó ni ilé náà yóo wá sọ fún alufaa pé, ‘Ó dàbí ẹni pé àrùn kan wà ní ilé mi.’
36 Kí alufaa pàṣẹ pé kí wọn kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà jáde, kí ó tó lọ yẹ àrùn náà wò; kí ó má baà pe gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà ní aláìmọ́; lẹ́yìn náà, kí alufaa lọ wo ilé náà.
37 Kí ó yẹ àrùn náà wò, bí ó bá jẹ́ pé lára ògiri ilé ni àrùn yìí wà, tí ibi tí ó wà lára ògiri náà dàbí àwọ̀ ewéko tabi tí ó pọ́n, tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì jìn ju ara ògiri lọ.