6 “Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ tọ ìbátan rẹ̀ lọ láti bá a lòpọ̀. Èmi ni OLUWA.
7 Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ bá ìyá rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé, bí ẹni ń tú baba ẹni síhòòhò ni, ìyá rẹ ni, o kò gbọdọ̀ tú ìyá rẹ síhòòhò.
8 O kò gbọdọ̀ bá aya baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé bí ẹni ń tú baba ẹni síhòòhò ni.
9 O kò gbọdọ̀ bá arabinrin rẹ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lobinrin, tabi ọmọ baba rẹ lobinrin, kì báà jẹ́ pé ilé ni wọ́n bí i sí tabi ìdálẹ̀.
10 O kò gbọdọ̀ bá ọmọ ọmọ rẹ lobinrin lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ obinrin tabi ọmọ ọmọ rẹ ọkunrin, nítorí ohun ìtìjú ni ó jẹ́ fún ọ, nítorí pé, ìhòòhò wọn jẹ́ ìhòòhò rẹ.
11 O kò gbọdọ̀ bá ọmọ tí aya baba rẹ bá bí fún baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, arabinrin rẹ ni.
12 O kò gbọdọ̀ bá arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹbí baba rẹ ni ó jẹ́.