4 “Ẹ kò gbọdọ̀ yipada kí ẹ lọ bọ oriṣa tabi kí ẹ yá ère kankan fún ara yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.
5 “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.
6 Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú ẹbọ náà gan-an tabi ní ọjọ́ keji rẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ohun tí ẹ fi rúbọ tán. Bí ohunkohun bá kù di ọjọ́ kẹta, sísun ni ẹ gbọdọ̀ dáná sun ún.
7 Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ́ ní ọjọ́ kẹta, ohun ìríra ni, kò sì ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́.
8 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ẹ́ yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí pé, ó ti ba ohun mímọ́ OLUWA jẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
9 “Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ, o kò gbọdọ̀ kórè títí kan ààlà. Lẹ́yìn tí o bá ti kórè tán, o kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn ohun tí o bá gbàgbé.
10 O kò gbọdọ̀ kórè gbogbo àjàrà rẹ tán patapata, o kò sì gbọdọ̀ ṣa àwọn èso tí ó bá rẹ̀ sílẹ̀ ninu ọgbà àjàrà rẹ, o níláti fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ.