1 OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí ikú àwọn eniyan rẹ̀.
2 Àfi ti àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ wọn, bíi ìyá tabi baba rẹ̀; tabi ọmọ tabi arakunrin rẹ̀,
3 tabi ti arabinrin rẹ̀ tí kò tíì mọ ọkunrin, (tí ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀, nítorí pé kò tíì ní ọkọ, nítorí tirẹ̀, alufaa náà lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́).
4 Kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́, nítorí olórí ló jẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
5 “Alufaa kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ débi pé kí ó fá irun rẹ̀, tabi kí ó gé ẹsẹ̀ irùngbọ̀n rẹ̀ tabi kí ó fi abẹ ya ara rẹ̀.
6 Wọ́n níláti jẹ́ mímọ́ fún Ọlọrun wọn, wọn kò sì gbọdọ̀ sọ orúkọ Ọlọrun wọn di aláìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA; èyí tíí ṣe oúnjẹ Ọlọrun wọn, nítorí náà wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.