3 Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan.
4 Ọlọrun lọ bá a níbẹ̀, Balaamu sì sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti tẹ́ pẹpẹ meje, mo sì ti fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.”
5 OLUWA bá rán Balaamu pada sí Balaki, ó sọ ohun tí yóo sọ fún un.
6 Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà.
7 Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Láti Aramu, Balaki mú mi wá,ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn.Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu,kí o sì fi Israẹli ré.’
8 Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè,báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e?Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé,báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè?
9 Mo rí wọn láti òkè gíga,mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè.Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé;wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.