4 Ọlọrun lọ bá a níbẹ̀, Balaamu sì sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti tẹ́ pẹpẹ meje, mo sì ti fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.”
5 OLUWA bá rán Balaamu pada sí Balaki, ó sọ ohun tí yóo sọ fún un.
6 Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà.
7 Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Láti Aramu, Balaki mú mi wá,ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn.Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu,kí o sì fi Israẹli ré.’
8 Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè,báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e?Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé,báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè?
9 Mo rí wọn láti òkè gíga,mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè.Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé;wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
10 Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn?Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli?Jẹ́ kí n kú ikú olódodo,kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.”