14 “Bí àlejò kan bá wà ní ààrin yín tí ó sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, yóo ṣe é gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀. Òfin ati ìlànà kan náà ni ó wà fún gbogbo yín, ati onílé ati àlejò.”
15 Ní ọjọ́ tí wọn pa Àgọ́ Àjọ, èyí tí í ṣe Àgọ́ Ẹ̀rí, ìkùukùu bò ó. Ní alẹ́, ìkùukùu náà dàbí ọ̀wọ̀n iná.
16 Ìkùukùu ni lọ́sàn-án, ṣugbọn ní alẹ́, ó dàbí ọ̀wọ̀n iná. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì máa ń rí nígbà gbogbo.
17 Nígbà tí ìkùukùu yìí bá kúrò ní orí Àgọ́ Àjọ àwọn ọmọ Israẹli yóo tú àgọ́ wọn palẹ̀, wọn yóo sì lọ tún un pa níbi tí ìkùukùu náà bá ti dúró.
18 Àṣẹ OLUWA ni àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé láti tú àgọ́ wọn palẹ̀ ati láti tún àgọ́ wọn pa. Níwọ̀n ìgbà tí ìkùukùu náà bá ti wà ní orí Àgọ́ Àjọ, àwọn ọmọ Israẹli yóo dúró ninu àgọ́ wọn.
19 Nígbà tí ìkùukùu náà tilẹ̀ dúró pẹ́ ní orí Àgọ́, àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìgbọràn sí OLUWA, wọ́n dúró ninu àgọ́ wọn.
20 Ìgbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ìkùukùu náà yóo dúró lórí Àgọ́ Àjọ fún ọjọ́ bíi mélòó péré. Sibẹsibẹ, àṣẹ OLUWA ni àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé kì báà ṣe pé ó jẹ mọ́ pé kí wọn tú àgọ́ wọn palẹ̀ ni tabi pé kí wọ́n tún un pa.