21 Lẹ́yìn náà Samuẹli mú kí àwọn ìdílé ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini tò kọjá, gègé sì mú ìdílé Matiri. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé Matiri bẹ̀rẹ̀ sí tò kọjá, gègé sì mú Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣugbọn wọn kò rí i nígbà tí wọ́n wá a.
22 Wọ́n bi OLUWA pé, “Àbí ọkunrin náà kò wá ni?”OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ó ti farapamọ́ sí ààrin àwọn ẹrù.”
23 Wọ́n sáré lọ mú un jáde láti ibẹ̀. Nígbà tí ó dúró láàrin wọn, kò sí ẹni tí ó ga ju èjìká rẹ̀ lọ ninu wọn.
24 Samuẹli bá wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹni tí OLUWA yàn nìyí. Kò sí ẹnikẹ́ni láàrin wa tí ó dàbí rẹ̀.”Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.”
25 Samuẹli ṣe àlàyé àwọn ẹ̀tọ́ ati iṣẹ́ ọba fún àwọn eniyan náà. Ó kọ àwọn àlàyé náà sinu ìwé kan, ó sì gbé e siwaju OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó ní kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀.
26 Saulu náà bá pada lọ sí ilé rẹ̀ ní Gibea. Àwọn akọni ọkunrin bíi mélòó kan tí Ọlọrun ti fi sí ní ọkàn bá Saulu lọ.
27 Ṣugbọn àwọn oníjàngbọ̀n kan dáhùn pé, “Báwo ni eléyìí ṣe lè gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣugbọn Saulu kò sọ̀rọ̀.