40 Ó tún wá, ó rí i pé wọ́n tún ń sùn, nítorí pé oorun ń kùn wọ́n pupọ. Wọn kò wá mọ ìdáhùn tí wọn ì bá fi fún un mọ́.
41 Ó pada wá ní ẹẹkẹta, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣì wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń gbádùn ìsinmi yín? Àbùṣe bùṣe! Àkókò náà tó. Wọn yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.
42 Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ. Ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ti súnmọ́ tòsí.”
43 Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila dé, pẹlu àwọn eniyan tí ó mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà.
44 Ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá ti fi àmì fún wọn. Ó ní, “Ẹni tí mo bá kí, tí mo fi ẹnu kàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ọkunrin náà. Ẹ mú un, kí ẹ fà á lọ, ẹ má jẹ́ kí ó bọ́.”
45 Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé, Judasi lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó kí i, ó ní, “Olùkọ́ni!” Ó sì da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.
46 Àwọn tí ó bá a wá bá ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un.