10 Benhadadi si ranṣẹ si i, o si wipe, Ki awọn oriṣa ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu bi ẽkuru Samaria yio to fun ikunwọ fun gbogbo enia ti ntẹle mi.
11 Ọba Israeli si dahùn, o si wipe, Wi fun u pe, Má jẹ ki ẹniti nhamọra, ki o halẹ bi ẹniti mbọ́ ọ silẹ,
12 O si ṣe, nigbati Benhadadi gbọ́ ọ̀rọ yi, bi o ti nmuti, on ati awọn ọba ninu agọ, li o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ tẹ́gun si ilu na.
13 Si kiyesi i, woli kan tọ̀ Ahabu, ọba Israeli wá, wipe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ ri gbogbo ọ̀pọlọpọ yi? kiyesi i, emi o fi wọn le ọ lọwọ loni; iwọ o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.
14 Ahabu wipe, Nipa tani? On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nipa awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko. Nigbana li o wipe, Tani yio wé ogun na? On si dahùn pe: Iwọ.
15 Nigbana li o kà awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko, nwọn si jẹ igba o le mejilelọgbọn: lẹhin wọn li o si kà gbogbo awọn enia, ani gbogbo awọn ọmọ Israeli jẹ ẹdẹgbarin.
16 Nwọn si jade lọ li ọjọ-kanri. Ṣugbọn Benhadadi mu amupara ninu agọ, on, ati awọn ọba, awọn ọba mejilelọgbọn ti nràn a lọwọ.