29 Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, goke lọ si Ramoti-Gileadi.
30 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ija; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Ọba Israeli si pa aṣọ dà, o si lọ si oju ijà.
31 Ṣugbọn ọba Siria paṣẹ fun awọn olori-kẹkẹ́ rẹ̀, mejilelọgbọn, ti o ni aṣẹ lori kẹkẹ́ rẹ̀ wipe, Máṣe ba ẹni-kekere tabi ẹni-nla jà, bikoṣe ọba Israeli nikan.
32 O si ṣe, bi awọn olori-kẹkẹ́ ti ri Jehoṣafati, nwọn si wipe, ọba Israeli li eyi. Nwọn si yà sapakan lati ba a jà: Jehoṣafati si kigbe.
33 O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ woye pe, kì iṣe ọba Israeli li eyi, nwọn si pada kuro lẹhin rẹ̀.
34 Ọkunrin kan si fà ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin; nitorina li o ṣe wi fun olutọju-kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ́ rẹ dà, ki o si mu mi jade kuro ninu ogun; nitoriti emi gbọgbẹ.
35 Ogun na si le li ọjọ na: a si dá ọba duro ninu kẹkẹ́ kọju si awọn ara Siria, o si kú li aṣalẹ, ẹ̀jẹ si ṣàn jade lati inu ọgbẹ na si ãrin kẹkẹ́ na.