39 O si fi ijoko marun si apa ọtún ile na, ati marun si apa òsi ile na: o si gbe agbada-nla ka apa ọ̀tún ile na, si apa ila-õrun si idojukọ gusu:
40 Hiramu si ṣe ikoko ati ọkọ́, ati awo-koto. Bẹ̃ni Hiramu si pari gbogbo iṣẹ ti o ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba:
41 Ọwọ̀n meji, ati ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n meji; ati iṣẹ àwọ̀n meji lati bò ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n;
42 Ati irinwo pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n meji, ọ̀wọ́ meji pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n kan, lati bò awọn ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n;
43 Ati ijoko mẹwa, ati agbada mẹwa lori awọn ijoko na.
44 Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ agbada nla.
45 Ati ikoko, ati ọkọ́, ati awo-koto; ati gbogbo ohun-elo wọnyi ti Hiramu ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba, jẹ ti idẹ didan.