10 O si ṣe lẹhin ogún ọdun, nigbati Solomoni ti kọ́ ile mejeji tan, ile Oluwa, ati ile ọba.
11 Hiramu, ọba Tire ti ba Solomoni wá igi kedari ati igi firi, ati wura gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀, nigbana ni Solomoni ọba fun Hiramu ni ogún ilu ni ilẹ Galili.
12 Hiramu si jade lati Tire wá lati wò ilu ti Solomoni fi fun u: nwọn kò si wù u.
13 On si wipe, Ilu kini wọnyi ti iwọ fi fun mi, arakunrin mi? O si pè wọn ni ilẹ Kabulu titi fi di oni yi.
14 Hiramu si fi ọgọta talenti wura ranṣẹ si ọba.
15 Idi awọn asìnru ti Solomoni kojọ ni eyi; lati kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀, ati Millo, ati odi Jerusalemu, ati Hasori ati Megiddo, ati Geseri.
16 Farao, ọba Egipti ti goke lọ, o si ti kó Geseri, o si ti fi iná sun u, o si ti pa awọn ara Kenaani ti ngbe ilu na, o si fi ta ọmọbinrin rẹ̀, aya Solomoni li ọrẹ.