1 SAULU si sọ fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o pa Dafidi.
2 Ṣugbọn Jonatani ọmọ Saulu fẹràn Dafidi pupọ: Jonatani si sọ fun Dafidi pe, Saulu baba mi nwá ọ̀na ati pa ọ, njẹ, mo bẹ̀ ọ, kiyesi ara rẹ titi di owurọ, ki o si joko nibi ikọ̀kọ, ki o si sa pamọ.
3 Emi o si jade lọ, emi o si duro ti baba mi li oko na nibiti iwọ gbe wà, emi o si ba baba mi sọ̀rọ nitori rẹ; eyiti emi ba si ri, emi o sọ fun ọ.
4 Jonatani si sọ̀rọ Dafidi ni rere fun Saulu baba rẹ̀, o si wi fun u pe, Ki a máṣe jẹ ki ọba ki o ṣẹ̀ si iranṣẹ rẹ̀, si Dafidi; nitori kò ṣẹ̀ ọ, ati nitoripe iṣẹ rẹ̀ dara gidigidi fun ọ.
5 Nitoriti o mu ẹmi rẹ̀ lọwọ rẹ̀, o si pa Filistini na, Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla fun gbogbo Israeli: iwọ ri i, o si yọ̀: njẹ, nitori kini iwọ o ṣe dẹṣẹ̀ si ẹjẹ alaiṣẹ, ti iwọ o fi pa Dafidi laiṣẹ?
6 Saulu si gbọ́ ohùn Jonatani: Saulu si bura pe, Bi Oluwa ti wà lãye a ki yio pa a.