12 Dafidi si pa ọ̀rọ wọnyi mọ li ọkàn rẹ̀, o si bẹ̀ru Akiṣi ọba Gati gidigidi.
13 On si pa iṣe rẹ̀ dà niwaju wọn, o si sọ ara rẹ̀ di aṣiwere li ọwọ́ wọn, o si nfi ọwọ́ rẹ̀ há ilẹkun oju ọ̀na, o si nwà itọ́ si irungbọn rẹ̀.
14 Nigbana ni Akiṣi wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ẹnyin ri pe ọkunrin na nhuwà aṣiwere; njẹ nitori kini ẹnyin ṣe mu u tọ̀ mi wá?
15 Mo ha ni aṣiwere fi ṣe? ti ẹnyin fi mu eyi tọ̀ mi wá lati hu iwa aṣiwere niwaju mi? eleyi yio ha wọ inu ile mi?