1 DAFIDI si kuro nibẹ, o si sa si iho Adullamu; nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ati idile baba rẹ̀ si gbọ́ ọ, nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ nibẹ.
2 Olukuluku ẹniti o ti wà ninu ipọnju, ati olukuluku ẹniti o ti jẹ gbesè, ati olukuluku ẹniti o wà ninu ibanujẹ, si ko ara wọn jọ sọdọ rẹ̀, on si jẹ olori wọn: awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ si to iwọn irinwo ọmọkunrin.
3 Dafidi si ti ibẹ̀ na lọ si Mispe ti Moabu: on si wi fun ọba Moabu pe, Jẹ ki baba ati iya mi, emi bẹ̀ ọ, wá ba ọ gbe, titi emi o fi mọ̀ ohun ti Ọlọrun yio ṣe fun mi.
4 O si mu wọn wá siwaju ọba Moabu; nwọn si ba a gbe ni gbogbo ọjọ ti Dafidi fi wà ninu ihò na.
5 Gadi woli si wi fun Dafidi pe, Máṣe gbe inu ihò na; yẹra, ki o si lọ si ilẹ Juda. Nigbana ni Dafidi si yẹra, o si lọ sinu igbo Hareti.
6 Saulu si gbọ́ pe a ri Dafidi ati awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀; Saulu si ngbe ni Gibea labẹ igi kan ni Rama; ọkọ̀ rẹ̀ si mbẹ lọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ si duro tì i;