17 Oluwa si ṣe fun ara rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Oluwa si yà ijọba na kuro li ọwọ́ rẹ, o si fi fun aladugbo rẹ, ani Dafidi.
18 Nitoripe iwọ kò gbọ́ ohùn Oluwa, iwọ kò si ṣe iṣẹ ibinu rẹ̀ si Amaleki, nitorina li Oluwa si ṣe nkan yi si ọ loni yi:
19 Oluwa yio si fi Israeli pẹlu iwọ le awọn Filistini lọwọ: li ọla ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio pẹlu mi: Oluwa yio si fi ogun Israeli le awọn Filistini lọwọ́.
20 Lojukanna ni Saulu ṣubu lulẹ gbọrọ bi o ti gùn, ẹ̀ru si bà a gidigidi, nitori ọ̀rọ Samueli; agbara kò si si fun u: nitoripe kò jẹun li ọjọ na t'ọsan t'oru.
21 Obinrin na si tọ Saulu wá, o si ri i pe o wà ninu ibanujẹ pupọ, o si wi fun u pe, Wõ, iranṣẹbinrin rẹ ti gbọ́ ohùn rẹ, emi si ti fi ẹmi mi si ọwọ́ mi, emi si ti gbọ́ ọ̀rọ ti iwọ sọ fun mi.
22 Njẹ, nisisiyi, emi bẹ ọ, gbọ́ ohùn iranṣẹbinrin rẹ, emi o si fi onjẹ diẹ siwaju rẹ; si jẹun, iwọ o si li agbara, nigbati iwọ ba nlọ li ọ̀na.
23 Ṣugbọn on kọ̀, o si wipe, Emi kì yio jẹun. Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ̀, pẹlu obinrin na si rọ̀ ọ; on si gbọ́ ohùn wọn. O si dide kuro ni ilẹ, o si joko lori akete.