6 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru nitori wọn: nitori li ọla li akokò yi emi o fi gbogbo wọn tọrẹ niwaju Israeli ni pipa: iwọ o já patì ẹṣin wọn, iwọ o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn.
7 Bẹ̃ni Joṣua, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, yọ si wọn lojijì ni ibi omi Meromu, nwọn si kọlù wọn.
8 OLUWA si fi wọn lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn, nwọn si lé wọn titi dé Sidoni nla ati titi dé Misrefoti-maimu, ati dé afonifoji Mispa ni ìha ìla-õrùn; nwọn si pa wọn tobẹ̃ ti kò kù ẹnikan silẹ fun wọn.
9 Joṣua si ṣe si wọn gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o já patì ẹṣin wọn, o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn.
10 Joṣua si pada li akokò na, o si kó Hasoru, o si fi idà pa ọba rẹ̀: nitori li atijọ́ rí Hasoru li olori gbogbo ilẹ-ọba wọnni.
11 Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, nwọn run wọn patapata: a kò kù ẹnikan ti nmí silẹ: o si fi iná kun Hasoru.
12 Ati gbogbo ilu awọn ọba wọnni, ati gbogbo ọba wọn, ni Joṣua kó, o si fi oju idà kọlù wọn, o si pa wọn run patapata, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti palaṣẹ.