1 IPÍN awọn ọmọ Josefu yọ lati Jordani lọ ni Jeriko, ni omi Jeriko ni ìha ìla-õrùn, ani aginjù, ti o gòke lati Jeriko lọ dé ilẹ òke Beti-eli;
2 O si ti Beti-eli yọ si Lusi, o si kọja lọ si àgbegbe Arki dé Atarotu;
3 O si sọkalẹ ni ìha ìwọ-õrùn si àgbegbe Jafleti, dé àgbegbe Beti-horoni isalẹ, ani dé Geseri: o si yọ si okun.
4 Bẹ̃li awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu, gbà ilẹ-iní wọn.
5 Àla awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn li eyi: ani àla ilẹ-iní wọn ni ìha ìla-õrùn ni Atarotu-adari, dé Beti-horoni òke;