47 Awọn ọmọ Dani si gbọ̀n àla wọn lọ: awọn ọmọ Dani si gòke lọ ibá Leṣemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀, nwọn si pè Leṣemu ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn.
48 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.
49 Nwọn si pari pipín ilẹ na fun ilẹ-iní gẹgẹ bi àla rẹ̀; awọn ọmọ Israeli si fi ilẹ-iní kan fun Joṣua ọmọ Nuni lãrin wọn:
50 Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA, nwọn fun u ni ilu ti o bère, ani Timnati-sera li òke Efraimu: o si kọ ilu na, o si ngbé inu rẹ̀.
51 Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.