29 Ki Ọlọrun má jẹ ki awa ki o ṣọ̀tẹ si OLUWA, ki awa si pada li oni kuro lẹhin OLUWA, lati mọ pẹpẹ fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ ohunjije, tabi fun ẹbọ kan, lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa ti mbẹ niwaju agọ́ rẹ̀.
30 Nigbati Finehasi alufa, ati awọn olori ijọ, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli ti o wà pẹlu rẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ ti awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati awọn ọmọ Manasse sọ, o dùnmọ́ wọn.
31 Finehasi ọmọ Eleasari alufa si wi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Manasse pe, Li oni li awa mọ̀ pe OLUWA wà lãrin wa, nitoriti ẹnyin kò dẹ̀ṣẹ yi si OLUWA: nisisiyi ẹnyin yọ awọn ọmọ Israeli kuro lọwọ OLUWA.
32 Finehasi ọmọ Eleasari alufa, ati awọn olori, si pada lati ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati lati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ni ilẹ Gileadi, si ilẹ Kenaani, sọdọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si mú ìhin pada tọ̀ wọn wá.
33 Ohun na si dùnmọ́ awọn ọmọ Israeli; awọn ọmọ Israeli si fi ibukún fun Ọlọrun, nwọn kò si sọ ti ati gòke tọ̀ wọn lọ ijà, lati run ilẹ na ninu eyiti awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ngbé.
34 Awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi si sọ pẹpẹ na ni Edi: nwọn wipe, Nitori ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin pe OLUWA on li Ọlọrun.