2 Ọba 17:30-36 BMY

30 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Bábílónì ṣe àgọ́ àwọn wúndíá, àwọn ọkùnrin láti Kútì ṣe Négálì, àti àwọn ènìyàn láti Hámátì ṣe Áṣímà;

31 Àti àwọn ará Áfà ṣe Nébíhásì àti Tárítakì, àti àwọn ará Ṣéfárífáímù ṣun àwọn ọmọ wọn níná gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Adiramélékì àti Anamélékì, àwọn òrìṣà Ṣéfárfáímù.

32 Wọ́n sin Olúwa, ṣùgbọ́n wọ́n sì tún yan gbogbo ẹgbẹ́ tí ènìyàn wọn láti ṣe iṣẹ́ oyè fún wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ibi gíga.

33 Wọ́n sin Olúwa ṣùgbọ́n wọ́n sin òrìṣà wọn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àṣà orílẹ̀ èdè wọn láti ibi tí wọ́n ti gbé wọn wá.

34 Láti ìgbà náà wá àwọn àlùfáà wọn ṣe bí ti àtẹ̀yìnwá. Wọn kò sin Olúwa tàbí kí wọ́n fi ara mọ́ ìlànà àti àṣẹ àti òfin tí Olúwa fi fún ìránṣẹ́ Jákọ́bù, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.

35 Nígbà tí Olúwa ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe sin òrìṣà mìíràn tàbí tẹríba fún wọn, sìn wọ́n tàbí kí ẹ rúbọ sí wọn.

36 Ṣùgbọ́n Olúwa, ẹni tí ó mú yín gòkè jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú agbára ńlá àti nínà apá, òun ni ẹni náà tí ó yẹ kí ẹ sìn. Òun ni ẹni tí ó yẹ kí ẹ tẹríba fún àti sí òun ni kí ẹ rúbọ fún.