1 Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Gbé síléètì òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún figi kan àpótí kan.
2 Èmi yóò sì tún ọ̀rọ̀ tí ó wà lórí síléètì àkọ́kọ́ tí o fọ́ kọ sórí rẹ̀. Kí o sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”
3 Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kaṣíà, mo sì gbẹ́ síléètì òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú síléètì méjèèjì lọ́wọ́ mí.
4 Olúwa tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí síléétì wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. Olúwa sì fi wọ́n fún mi.