14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.
15 Ṣíbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀ èdè títí di òní.
16 Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, (Ẹ wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́) kí ẹ má sì se jẹ́ olóríkunkun mọ́ láti òní lọ.
17 Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojú ṣàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
18 Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àlejò, Óun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn.
19 Ẹ gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn àlejò, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àlejò rí ní Éjíbítì.
20 Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dì í mú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀.