17 Nígbà náà ni ìbínú Olúwa yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má baà rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí Olúwa fi fún un yín.
18 Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí àmì sórí ọwọ́ ọ yín, kí ẹ sì ṣo wọ́n mọ́ iwájú orí i yín.
19 Ẹ máa fí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.
20 Ẹ kọ wọ́n sí férémù ìlẹ̀kùn yín, àti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé e yín.
21 Kí ọjọ́ ọ yín àti ti àwọn ọmọ yín lè pọ̀ ní ilẹ̀ tí Olúwa ti búra láti fifún àwọn baba ńlá a yín, ní ìwọ̀n ìgbà tí ọ̀run wà lókè tí ayé sì ń bẹ ní ìṣàlẹ̀.
22 Bí ẹ bá farabalẹ̀ kíyèsí àwọn òfin tí mo ń fún un yín, láti tẹ̀lé: Láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti dìí mú ṣinṣin:
23 Olúwa yóò sì lé gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀nyí kúrò níwájú u yín. Ẹ ó sì gba orílẹ̀ èdè tí ó lágbára tí ó sì tóbi jù yín lọ.