2 Ẹ rántí lónìí pé kì í ṣe àwọn ọmọ yín, ni ó rí ìbáwí Olúwa Ọlọ́run yín; títóbi rẹ̀, ọwọ́ agbára rẹ̀, nína ọwọ́ rẹ̀;
3 iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ní àárin àwọn ará Éjíbítì: Sí Fáráò ọba Éjíbítì àti gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ̀.
4 Ohun tí ó ṣe sí àwọn jagunjagun Éjíbítì, sí kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́sin rẹ̀: bí ó se rì wọ́n sínú òkun pupa, bí wọ́n ṣe ń lé e yín tí Olúwa fi pa wọ́n run pátapáta títí di òní olónìí yìí.
5 Kì í ṣe àwọn ọmọ yín ni ó rí ohun tí ó ṣe fún un yín ní ihà, títí ẹ fi dé ìhín yìí,
6 ohun tí ó ṣe sí Dátanì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù, ẹ̀yà Rúbẹ́nì, bí ilẹ̀ ti lanu ní ojú gbogbo ará Ísírẹ́lì tí ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wọn, gbogbo àgọ́ ọ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó jẹ́ tiwọn.
7 Ṣùgbọ́n ojú u yín gan an ni ó rí gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí tí Olúwa ti ṣe.
8 Nítorí náà, ẹ kíyèsí gbogbo àṣẹ tí mo ń fún un yín lónìí, kí ẹ ba à lè lágbára àti lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí ẹ ó la Jọ́dánì kọjá lọ.