Deutarónómì 15:2-8 BMY

2 Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é: Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbéṣè gbọdọ̀ fojú fo gbésè tí ó ti yá ará Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀. Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀: nítorí pé a ti kéde àkókò Olúwa láti fojú fo gbésè.

3 Ẹ lè béèrè ìsanpadà lọ́dọ̀ àjòjì. Ṣùgbọ́n ẹ fagi lé gbéṣè yóòwù kó jẹ́ tí arákùnrin yín jẹ yín.

4 Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò tọ́ sí nínú un yín, nítorí pé Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ilẹ̀ náà tí ó ń mú un yín lọ láti gbà bí ìní yín.

5 Kìkì bí ẹ bá gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí.

6 Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀ èdè tí yóò lè jọba lé e yín lórí.

7 Bí talákà kan bá wà láàrin àwọn arákùnrin yín ní èyíkèyí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí Olúwa yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe se àìláànú bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà.

8 Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò.