17 àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrin wọn gbọdọ̀ dúró níwájú Olúwa níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà.
18 Àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ ṣe ìwádìí fínnífínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀,
19 nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrin rẹ.
20 Àwọn ènìyàn tókù yóò gbọ́ nípa èyí, wọn yóò sì bẹ̀rù, kí irú nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ máa tún sẹ̀ mọ́ láàrin yín.
21 Má ṣe fi àánú hàn, ẹ̀mí fún ẹ̀mi, ojú fún ojú, eyín fún eyín, apá fún apá, ẹṣẹ̀ fún ẹṣẹ̀.