Deutarónómì 19:4-10 BMY

4 Èyí ni òfin nípa ẹni tí ó pa ẹlòmíràn tí ó sì sá ṣíbẹ̀ láti pa ẹ̀mí rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ó pa aládùúgbò láìmọ̀ọ́mọ̀ṣeé láì jẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.

5 Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè lọ sínú igbó pẹ̀lú aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó sì ti gbé àáké e rẹ̀ láti gé igi náà lulẹ̀, bí àáké náà bá yọ tí ó sì bà aládùúgbò rẹ̀, tí òun sì kú. Ọkùnrin yìí lè sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

6 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lè máa lépa rẹ̀ nínú ìbínú, kí ó sì lée bá nítorí pé ọ̀nà jìn, kí ó sì paá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ sí ikú, nígbà tí ó ṣeé sí aládùúgbò rẹ̀ láì jẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.

7 Ìdí nìyìí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara rẹ.

8 Tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn,

9 nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pa láṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta ṣọ́tọ̀.

10 Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bàá jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa.