23 Bí ó bá ṣẹlẹ̀ wí pé ọkùnrin kan pàde wúndíá tí a ti fi fún ni láti fẹ́ láàrin ìlú tí ó sì lòpọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀,
24 ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní ókúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrin rẹ.
25 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìgbẹ́ ní ó ti ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrín kan ti pàde ọmọbìnrin tí a ti fẹ́ sọ́nà tí o sì fi tagbára tagbára bá a se, ọkùnrin náà nìkan tí ó se èyí ni yóò kú.
26 Má se fi ohunkóhun ṣe ọmọbìnrin náà; kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ikú. Ẹjọ́ yìí rí bí i ti ẹnìkan tí a gbámú tí ó pa aládùúgbò rẹ̀.
27 Nítorí ọkùnrin náà rí ọmọbìnrin náà ní ìta ibodè, bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin àfẹ́sọ́nà kígbe, kò sí ẹnìkankan níbẹ̀ láti gbà á kalẹ̀.
28 Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin pàde wúndíá tí kò ì tí ì ní àfẹ́sọ́nà tí ó sì fi tipátipá báa ṣe tí a gbá wọn mú.
29 Ó ní láti san àádọ́ta fàdákà fún baba obìnrin náà, nítorí tí ó ti bà á jẹ́. Kò lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó sì wà láàyè.