7 O lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó baà lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn.
8 Nígbà tí o bá kọ́ ilé túntún, mọ odi yí òrùlé rẹ̀ ká nítorí kí o má baà mú ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ wá sórí ilẹ̀ rẹ bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú láti òrùlé.
9 Má ṣe gbin oríṣìí èso méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ; bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe èṣo oko tí o gbìn nìkan ṣùgbọ́n èṣo ọgbà àjàrà pẹ̀lú yóò bàjẹ́.
10 Má ṣe fi akọ màlúù àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tulẹ̀ pọ̀.
11 Má ṣe wọ aṣọ onírun àgùntàn àti aṣọ funfun papọ̀.
12 Kí o ṣe wajawaja sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ ìlẹ̀kẹ̀ rẹ.
13 Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, kórìíra rẹ̀,