14 Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú. Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pa láṣẹ fún mi.
15 Wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, ibùgbé mímọ́ rẹ, kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àwọn babańlá wa, ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.”
16 Olúwa Ọlọ́run rẹ pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin, kí o sì máa ṣe wọ́n pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo àyà rẹ.
17 Ìwọ jẹ́wọ́ Olúwa ní òní pé Olúwa ni Ọlọ́run rẹ, àti pé ìwọ yóò máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, àti pé ìwọ yóò máa pa ìlànà rẹ̀, àṣẹ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti pé ìwọ yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i.
18 Ní òní ni Olúwa jẹ́wọ́ rẹ pé ìwọ ni ènìyàn òun, ilé ìṣúra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí, àti pé ìwọ yóò máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́.
19 Òun sì jẹ́wọ́ pé, òun yóò gbé ọ sókè ju gbogbo orílẹ̀ èdè tí òun ti dá lọ, ní ìyìn, ní òkìkí àti ní ọlá; kí ìwọ kí ó le jẹ́ ènìyàn mímọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí.