13 Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ébálì láti gé ègún: Rúbẹ́nì, Gádì, àti Ásérì, àti Ṣébúlúnì, Dánì, àti Náfitanì.
14 Àwọn ẹ̀yà Léfì yóò ké sí gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì ní ohùn òkè:
15 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ onísọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
16 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójú ti baba tàbí ìyá rẹ̀”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
17 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládúgbò o rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
18 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó si afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
19 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àléjò, aláìní baba tàbí opó”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”