19 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àléjò, aláìní baba tàbí opó”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
20 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
21 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbalòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
22 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá a rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
23 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
24 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
25 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”