20 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
21 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbalòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
22 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá a rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
23 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
24 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
25 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
26 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa síse wọ́n.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”