1 Èyí ni àwọn ìpinnu májẹ̀mú tí Olúwa pa láṣẹ fún Mósè láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Móábù, ní àfikún májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú u wọn ní Hórébù,
2 Móṣè pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì sọ fún wọn wí pé:Ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ní Éjíbítì sí Fáráò àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.
3 Pẹ̀lú ojú ara rẹ ni ìwọ rí àwọn ìdánwò ńlá náà, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá.
4 Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ.
5 Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín sọ́nà ní ihà, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹṣẹ̀ rẹ.
6 O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn. Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ.
7 Nígbà tí o dé ibí yìí, Ṣíhónì ọba Hésíbónì àti Ógù ọba Básánì jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a sẹ́gun wọn.