11 (Ógù tí í ṣe ọba Báṣánì nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Ráfátì. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rábà ti àwọn Ámórì.)
12 Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Áréórì níbi odò Ánónì, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gílíádì pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.
13 Gbogbo ìyókù Gílíádì àti gbogbo Básánì, ní ilẹ̀ ọba Ógù ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè. (Gbogbo agbégbé Ágóbù ni Básánì tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Ráfátì.
14 Jáérì ọ̀kan nínú àwọn ìran Mánásè gba gbogbo agbégbé Ágóbù títí dé ààlà àwọn ará Gésúrì àti àwọn ará Mákátì; a sọ ibẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ torí èyí ni Básánì fi ń jẹ́ Hafoti-Jáírì títí di òní.)
15 Mo sì fi Gílíádì fún Mákírì,
16 ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti Gádì ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gílíádì lọ dé odò Ánónì (àárin odò náà sì jẹ́ ààlà) títí ó fi dé odò Jábókù. Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ámónì.
17 Apá ìwọ̀ óòrùn rẹ̀ ni Jọ́dánì, ní aginjù, láti Kínérétì títí dé òkun aginjù (Tí í ṣe òkun iyọ̀) ní ihà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.