44 Móṣè wà pẹ̀lú u Jóṣúà ọmọ Núnì ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn.
45 Nígbà tí Móṣè parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Ísírẹ́lì.
46 Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti ṣọ láàrin yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́ran àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.
47 Wọn kì í se ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jọ́dánì lọ láti gbà.”
48 Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Móṣè pé,
49 “Gòkè lọ sí Ábárímù sí òkè Nébò ní Móábù, tí ó kọjú sí Jẹ́ríkò, kí o sì wo ilẹ̀ Kénánì ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Isírẹ́lì, bí ìní i wọn.
50 Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Árónì ti kú ní orí òkè Hórù tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀.