11 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.
12 Kí ó má baà jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀,
13 nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i,
14 nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbé ga, tí ẹ ó sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá, nínú oko ẹrú.
15 Òun ni ó mú un yín la ihà ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òùngbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńláńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.
16 Ó fún yín ní mánà láti jẹ nínú ihà, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun báà le tẹ orí i yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó báà lè dára fún-un yín.
17 Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.”