14 nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbé ga, tí ẹ ó sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá, nínú oko ẹrú.
15 Òun ni ó mú un yín la ihà ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òùngbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńláńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.
16 Ó fún yín ní mánà láti jẹ nínú ihà, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun báà le tẹ orí i yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó báà lè dára fún-un yín.
17 Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.”
18 Ṣùgbọ́n ẹ rántí Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fún un yín lókun àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí.
19 Bí ẹ bá wá gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn, tí ẹ sì sìn wọ́n, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, Mo kìlọ̀ fún un yín pé rírun ni ẹ ó run.
20 Bí àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín lẹ́nu.