12 “Ọmọ aládé tó wà láàrin wọn yóò di ẹrù rẹ lé èjìká lálẹ́ yóò sì jáde lọ, òun náà yóò da ògiri lu kí ó le gba ibẹ̀ jáde. Yóò sì bo ojú rẹ̀ kí ó má ba à rí ilẹ̀.
13 N ó ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, N ó sì mú lọ sí Bábílónì, ní ilẹ̀ Kádíyà, ṣùgbọ́n kò ní fojú rí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí.
14 Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ (opá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀) ni N ó túká sí afẹ́fẹ́, n ó sì tún fi idà lé wọn kiri.
15 “Wọn ó sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo bá tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri.
16 Ṣùgbọ́n n ó ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, lọ́wọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè yìí. Nígbà náà ni wọn ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.”
17 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
18 “Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ̀n rìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà.