8 N ó lodi si írú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́nà òdì, n ó sì sọ ọ́ di àánú àti òwe. Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi. Nígbà náà, ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
9 “ ‘Bí wọ́n bá sì tan wòlíì náà láti sọtẹ́lẹ̀, Èmi Olúwa ló tan wòlíì náà, Èmi yóò nawọ́ sí i, èmi yóò sì pa á run kúrò láàrin àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.
10 Wọn yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn—ìjìyà kan náà là ó fún wòlíì àti ẹni tó lọ béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀.
11 Kí ilé Ísírẹ́lì má baà sìnà kúrò lọ́dọ̀ mi tàbí kí wọ́n má baà sọra wọn di aláìmọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n kí wọ́n le jẹ́ ènìyàn mi, kí Èmi náà sì le jẹ́ Ọlọ́run wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”
12 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
13 “Ọmọ ènìyàn bí orílẹ̀ èdè kan bá ṣẹ́ mí nípa ìwà àìṣòdodo, èmi yóò nawọ́ mi jáde sí wọn, láti gé ìpèsè oúnjẹ wọn, n ó rán ìyàn sí wọn, èmi yóò sì pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀,
14 bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí—Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù-tilẹ̀ wà nínú rẹ, ará wọn nìkan ni wọ́n lé gbà sílẹ̀ pẹ̀lú ìwà òdodo wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí.