Ísíkẹ́lì 20:28-34 BMY

28 Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí láti fún wọn, gbogbo igi ilẹ̀ gíga àti gbogbo igi to rúwé ni wọn tí ń rúbọ wọn ṣe irubọ to ń mú mi bínú, níbẹ̀ sì ni wọn ń ṣe òórùn dídùn wọn, ti wọn sì ń ta ọrẹ ohun mímu sílẹ̀.

29 Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé: Kí ní ibi gíga tí ẹ n lọ yìí?’ ” (Wọn sì ń pè ní Bámà di onì yìí.)

30 “Nítorí náà sọ fún ile Ísírẹ́lì: ‘Èyí ní ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Ṣe o fẹ bara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, to ń ṣe àgbèrè nípa tí tẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra?

31 Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, irúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú wọn la iná kọjá-ẹ ń tèṣíwájú láti bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, èmi ó wa jẹ ki ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi bí ilé Ísírẹ́lì? Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, N kò ní i jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.

32 “ ‘Ẹ̀yin wí pé, “Àwa fẹ dàbí àwọn orílẹ̀ èdè yóòkù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta.” Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá.

33 Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, ń ó jọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí ń ó nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi.

34 Èmi yóò mú yín jáde láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì ṣà yín jọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín sí pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde àti pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná ni.