31 Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, irúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú wọn la iná kọjá-ẹ ń tèṣíwájú láti bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, èmi ó wa jẹ ki ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi bí ilé Ísírẹ́lì? Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, N kò ní i jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.
32 “ ‘Ẹ̀yin wí pé, “Àwa fẹ dàbí àwọn orílẹ̀ èdè yóòkù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta.” Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá.
33 Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, ń ó jọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí ń ó nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi.
34 Èmi yóò mú yín jáde láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì ṣà yín jọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín sí pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde àti pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná ni.
35 Èmi yóò mú yín wá sí ihà àwọn orílẹ̀ èdè, níbẹ̀ ni ojúkójú ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ lé e yín lórí.
36 Bí mo ṣe ṣe idájọ́ àwọn baba yín nínú ihà nílẹ̀ Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe idájọ́ yín ní Olúwa Ọlọ́run wí.
37 Èmi yóò kíyèsí i yín bí mo ti mú un yín kọjá lábẹ́ ọ̀pá, èmi yóò sì mú yín wá sí abẹ́ ìdè májẹ̀mú