32 “ ‘Ẹ̀yin wí pé, “Àwa fẹ dàbí àwọn orílẹ̀ èdè yóòkù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta.” Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá.
33 Bí mo ti wà láàyè ní Olúwa Ọlọ́run wí, ń ó jọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí ń ó nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi.
34 Èmi yóò mú yín jáde láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì ṣà yín jọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín sí pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde àti pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná ni.
35 Èmi yóò mú yín wá sí ihà àwọn orílẹ̀ èdè, níbẹ̀ ni ojúkójú ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ lé e yín lórí.
36 Bí mo ṣe ṣe idájọ́ àwọn baba yín nínú ihà nílẹ̀ Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe idájọ́ yín ní Olúwa Ọlọ́run wí.
37 Èmi yóò kíyèsí i yín bí mo ti mú un yín kọjá lábẹ́ ọ̀pá, èmi yóò sì mú yín wá sí abẹ́ ìdè májẹ̀mú
38 Èmi yóò ṣa àwọn tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí mí kúrò láàrin yín. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé èmi yóò mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọn ń gbé, síbẹ̀ wọn kò ní dé ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ní Olúwa.